Numeri 11:17
Numbers 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú díẹ̀ nínú agbára Ẹ̀mí tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.
Numbers 11:17 in English
Numbers 11:17 · Berean Standard Bible
And I will come down and speak with you there, and I will take some of the Spirit that is on you and put that Spirit on them. They will help you bear the burden of the people, so that you do not have to bear it by yourself.
Context
15Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojúrere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.” 16Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú àádọ́rin ọkùnrin nínú àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrín àwọn ènìyàn wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi. 17Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú díẹ̀ nínú agbára Ẹ̀mí tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà. 18“Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Ejibiti jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́. 19Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.