Native Bible

Numbers 11:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan, títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ”

Numbers 11:20 in English

Numbers 11:20 · Berean Standard Bible

but for a whole month—until it comes out of your nostrils and makes you nauseous—because you have rejected the LORD, who is among you, and have cried out before Him, saying, ‘Why did we ever leave Egypt?’”

Context

18“Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Ejibiti jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́. 19Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán, 20ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan, títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ” 21Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’ 22Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.