Native Bible

Numbers 11:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú.

Numbers 11:10 in English

Numbers 11:10 · Berean Standard Bible

Then Moses heard the people of family after family weeping at the entrances to their tents, and the anger of the LORD was kindled greatly, and Moses was also displeased.

Context

8Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe. 9Nígbà tí ìrì bá ẹ̀ sí ibùdó lórí ni manna náà máa ń bọ́ pẹ̀lú rẹ̀. 10Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú. 11Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí. 12Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.