Native Bible

Numbers 11:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn.

Numbers 11:12 in English

Numbers 11:12 · Berean Standard Bible

Did I conceive all these people? Did I give them birth, so that You should tell me, ‘Carry them in your bosom, as a nurse carries an infant,’ to the land that You swore to give their fathers?

Context

10Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú. 11Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí. 12Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn. 13Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sọkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’ 14Èmi nìkan kò lè dágbé wàhálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹrù wọn ti wúwo jù fún mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.