Nehemiah 7:69
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720).
Nehemiah 7:69 in English
Nehemiah 7:69 · Berean Standard Bible
435 camels, and 6,720 donkeys.
Context
67yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245). 68Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245); 69ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720). 70Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. 71Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá (2,200) mina fàdákà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.