Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245);

Nehemiah 7:68 in English

Nehemiah 7:68 · Berean Standard Bible

They had 736 horses, 245 mules, *

Context

66Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360), 67yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245). 68Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245); 69ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720). 70Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.