Nehemiah 3:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Refaiah ọmọ Huri, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe.
Nehemiah 3:9 in English
Nehemiah 3:9 · Berean Standard Bible
Next to them, Rephaiah son of Hur, ruler of a half-district of Jerusalem, made repairs;
Context
7Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gibeoni àti Mispa; Melatiah ti Gibeoni àti Jadoni ti Meronoti; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Eufurate. 8Usieli ọmọ Harhiah, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananiah, ọ̀kan lára àwọn tí ó ń ṣe tùràrí, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jerusalẹmu padà bọ̀ sípò títí dé Odi gbígbòòrò. 9Refaiah ọmọ Huri, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe. 10Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jedaiah ọmọ Haramafu tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hattusi ọmọ Haṣbneiah sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ. 11Malkiah ọmọ Harimu àti Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti ilé ìṣọ́ ìléru.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.