Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Usieli ọmọ Harhiah, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananiah, ọ̀kan lára àwọn tí ó ń ṣe tùràrí, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jerusalẹmu padà bọ̀ sípò títí dé Odi gbígbòòrò.

Nehemiah 3:8 in English

Nehemiah 3:8 · Berean Standard Bible

Next to them, Uzziel son of Harhaiah, one of the goldsmiths, made repairs, and next to him, Hananiah son of the perfumer made repairs. They fortified Jerusalem as far as the Broad Wall.

Context

6Jehoida ọmọ Pasea àti Meṣullamu ọmọ Besodeiah ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn. 7Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gibeoni àti Mispa; Melatiah ti Gibeoni àti Jadoni ti Meronoti; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Eufurate. 8Usieli ọmọ Harhiah, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananiah, ọ̀kan lára àwọn tí ó ń ṣe tùràrí, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jerusalẹmu padà bọ̀ sípò títí dé Odi gbígbòòrò. 9Refaiah ọmọ Huri, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe. 10Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jedaiah ọmọ Haramafu tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hattusi ọmọ Haṣbneiah sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.