Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jehoida ọmọ Pasea àti Meṣullamu ọmọ Besodeiah ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.

Nehemiah 3:6 in English

Nehemiah 3:6 · Berean Standard Bible

The Jeshanah Gate * was repaired by Joiada son of Paseah and Meshullam son of Besodeiah. They laid its beams and installed its doors, bolts, and bars.

Context

4Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Meṣullamu ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn mọ. Bákan náà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sadoku ọmọ Baanah náà tún odi mọ. 5Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tekoa tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn. 6Jehoida ọmọ Pasea àti Meṣullamu ọmọ Besodeiah ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn. 7Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gibeoni àti Mispa; Melatiah ti Gibeoni àti Jadoni ti Meronoti; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Eufurate. 8Usieli ọmọ Harhiah, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananiah, ọ̀kan lára àwọn tí ó ń ṣe tùràrí, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jerusalẹmu padà bọ̀ sípò títí dé Odi gbígbòòrò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.