Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.

Nehemiah 13:17 in English

Nehemiah 13:17 · Berean Standard Bible

Then I rebuked the nobles of Judah and asked, “What is this evil you are doing—profaning the Sabbath day?

Context

15Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà. 16Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda. 17Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́. 18Ṣé àwọn baba ńlá yín kò ha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá orí wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú sókè sí i sórí Israẹli nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.” 19Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì ṣí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.