Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà.

Nehemiah 13:15 in English

Nehemiah 13:15 · Berean Standard Bible

In those days I saw people in Judah treading winepresses on the Sabbath and bringing in grain and loading it on donkeys, along with wine, grapes, and figs. All kinds of goods were being brought into Jerusalem on the Sabbath day. So I warned them against selling food on that day.

Context

13Mo sì fi àlùfáà Ṣelemiah, Sadoku akọ̀wé àti ọmọ Lefi kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedaiah ṣe alákòóso àwọn yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. Mo sì yan Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah bí olùrànlọ́wọ́ ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn. 14Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo. 15Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà. 16Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda. 17Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.