Nehemiah 13:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda.
Nehemiah 13:16 in English
Nehemiah 13:16 · Berean Standard Bible
Additionally, men of Tyre who lived there were importing fish and all kinds of merchandise and selling them on the Sabbath to the people of Judah in Jerusalem.
Context
14Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo. 15Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà. 16Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda. 17Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́. 18Ṣé àwọn baba ńlá yín kò ha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá orí wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú sókè sí i sórí Israẹli nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.