Nehemiah 10:32
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé, a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa:
Nehemiah 10:32 in English
Nehemiah 10:32 · Berean Standard Bible
We also place ourselves under the obligation to contribute a third of a shekel * yearly for the service of the house of our God:
Context
30“A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa. 31“Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́. 32“Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé, a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa: 33nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa. 34“Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.