Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.

Nehemiah 10:31 in English

Nehemiah 10:31 · Berean Standard Bible

When the people of the land bring merchandise or any kind of grain to sell on the Sabbath day, we will not buy from them on a Sabbath or holy day. Every seventh year we will let the fields lie fallow, and will cancel every debt.

Context

29gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára. 30“A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa. 31“Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́. 32“Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé, a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa: 33nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.