Native Bible

Mark 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà.

Mark 8:7 in English

Mark 8:7 · Berean Standard Bible

They also had a few small fish, and Jesus blessed them and ordered that these be set before them as well.

Context

5Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?” Wọ́n fèsì pé, “Ìṣù àkàrà méje.” 6Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 7Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà. 8Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún. 9Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì (4,000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.