Marku 8:5
Mark 8:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?” Wọ́n fèsì pé, “Ìṣù àkàrà méje.”
Mark 8:5 in English
Mark 8:5 · Berean Standard Bible
“How many loaves do you have?” Jesus asked. “Seven,” they replied.
Context
3Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.” 4Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?” 5Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?”
Wọ́n fèsì pé, “Ìṣù àkàrà méje.” 6Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 7Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.