Native Bible

Mark 8:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn Farisi tọ Jesu wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ́n béèrè fún àmì láti ọ̀run.

Mark 8:11 in English

Mark 8:11 · Berean Standard Bible

Then the Pharisees came and began to argue with Jesus, testing Him by demanding from Him a sign from heaven.

Context

9Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì (4,000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ. 10Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jesu wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dalmanuta. 11Àwọn Farisi tọ Jesu wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ́n béèrè fún àmì láti ọ̀run. 12Jesu mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì? Lóòótọ́ ni mo sọ fún un yín kò si àmì tí a ó fi fún ìran yín.” 13Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.