Native Bible

Mark 7:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà,

Mark 7:21 in English

Mark 7:21 · Berean Standard Bible

For from within the hearts of men come evil thoughts, sexual immorality, theft, murder, adultery,*

Context

19Nítorí tí kò lọ sínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n sínú ara, a sì yà á jáde, a sì gbá gbogbo oúnjẹ dànù.” (Nípa sísọ èyí, Jesu fihàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”) 20Nígbà náà, ó fi kún un pé, “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọ ni di aláìmọ́. 21Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, 22ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara-ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. 23Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.