Marku 6:13
Mark 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.
Mark 6:13 in English
Mark 6:13 · Berean Standard Bible
They also drove out many demons and healed many of the sick, anointing them with oil.
Context
11Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.” 12Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn. 13Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá. 14Láìpẹ́, ọba Herodu gbọ́ nípa Jesu, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi jíǹde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ.” 15Àwọn mìíràn wí pé, “Elijah ní.”
Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.