Native Bible

Mark 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.”

Mark 6:11 in English

Mark 6:11 · Berean Standard Bible

If anyone will not welcome you or listen to you, shake the dust off your feet when you leave that place, as a testimony against them.”*

Context

9Wọn kò tilẹ̀ gbọdọ̀ mú ìpààrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́. 10Jesu wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe sípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà. 11Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.” 12Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn. 13Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.