Native Bible

Mark 2:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò ti ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀?

Mark 2:25 in English

Mark 2:25 · Berean Standard Bible

Jesus replied, “Have you never read what David did when he and his companions were hungry and in need?

Context

23Ó sì ṣe ni ọjọ́ ìsinmi, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrín oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọkà. 24Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.” 25Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò ti ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀? 26Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Abiatari olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ àkàrà ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.” 27Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, “Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ́ ìsinmi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.