Native Bible

Mark 2:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe ni ọjọ́ ìsinmi, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrín oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọkà.

Mark 2:23 in English

Mark 2:23 · Berean Standard Bible

One Sabbath Jesus was passing through the grainfields, and His disciples began to pick the heads of grain as they walked along.

Context

21“Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, bí ó ba ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tuntun tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fàya kúrò lára ògbólógbòó, yíya rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù. 22Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì tuntun sínú ìgò wáìnì ògbólógbòó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a sì dàànù, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.” 23Ó sì ṣe ni ọjọ́ ìsinmi, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrín oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọkà. 24Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.” 25Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò ti ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.