Native Bible

Mark 2:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”

Mark 2:24 in English

Mark 2:24 · Berean Standard Bible

So the Pharisees said to Him, “Look, why are they doing what is unlawful on the Sabbath?”

Context

22Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì tuntun sínú ìgò wáìnì ògbólógbòó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a sì dàànù, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.” 23Ó sì ṣe ni ọjọ́ ìsinmi, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrín oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọkà. 24Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.” 25Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò ti ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀? 26Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Abiatari olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ àkàrà ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.