Native Bible

Mark 14:66 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò yìí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsi í tí Peteru ń yáná.

Mark 14:66 in English

Mark 14:66 · Berean Standard Bible

While Peter was in the courtyard below, one of the servant girls of the high priest came down

Context

64Ẹ̀yin fúnra yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?” Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.” 65Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú. 66Ní àkókò yìí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsi í tí Peteru ń yáná. 67Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ti yáná, Ó tẹjúmọ́ ọn. Ó sì sọ gbangba pé, “Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jesu ara Nasareti.” 68Ṣùgbọ́n Peteru sẹ́, ó ni, “N kò mọ Jesu náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Peteru sì jáde lọ sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.