Marku 14:64
Mark 14:64 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin fúnra yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?” Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.”
Mark 14:64 in English
Mark 14:64 · Berean Standard Bible
You have heard the blasphemy. What is your verdict?” And they all condemned Him as deserving of death.
Context
62Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni, ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.” 63Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? 64Ẹ̀yin fúnra yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”
Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.” 65Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú. 66Ní àkókò yìí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsi í tí Peteru ń yáná.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.