Marku 14:63
Mark 14:63 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún?
Mark 14:63 in English
Mark 14:63 · Berean Standard Bible
At this, the high priest tore his clothes and declared, “Why do we need any more witnesses?
Context
61Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́.
Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?” 62Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni, ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.” 63Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? 64Ẹ̀yin fúnra yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”
Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.” 65Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.