Native Bible

Mark 14:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”

Mark 14:25 in English

Mark 14:25 · Berean Standard Bible

Truly I tell you, I will no longer drink of the fruit of the vine until that day when I drink it anew in the kingdom of God.”

Context

23Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀. 24Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. 25Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.” 26Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè olifi lọ. 27Jesu sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ó sa kúrò lọ́dọ̀ mi, a ti kọ̀wé rẹ pé, “ ‘Èmi yóò lu olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.