Marku 13:31
Mark 13:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.
Mark 13:31 in English
Mark 13:31 · Berean Standard Bible
Heaven and earth will pass away, but My words will never pass away.
Context
29Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ ba ri àwọn ohun wọ̀nyí ti n ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tán, bi ìgbà tí ó wà lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. 30Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ìran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ. 31Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun. 32“Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe baba nìkan. 33Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró wámú, kí ẹ sì máa gbàdúrà, nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò ná yóò dé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.