Native Bible

Mark 10:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu béèrè pé, “Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín?”

Mark 10:36 in English

Mark 10:36 · Berean Standard Bible

“What do you want Me to do for you?” He inquired.

Context

34Wọn yóò fi ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàṣán wọn. Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde.” 35Lẹ́yìn èyí, Jakọbu àti Johanu, àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa.” 36Jesu béèrè pé, “Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín?” 37Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, “Jẹ́ kí ọ̀kan nínú wa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ẹnìkejì ní ọwọ́ òsì nínú ògo rẹ!” 38Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitiisi yín pẹ̀lú irú ì bamitiisi ìjìyà tí a ó fi bamitiisi mi?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.