Native Bible

Mark 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà, Jesu gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.

Mark 10:16 in English

Mark 10:16 · Berean Standard Bible

And He took the children in His arms, placed His hands on them, and blessed them.

Context

14Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 15Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò le è wọ inú rẹ̀.” 16Nígbà náà, Jesu gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn. 17Bí Jesu ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” 18Jesu béèrè pé, arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.