Native Bible

Mark 10:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu béèrè pé, arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere.

Mark 10:18 in English

Mark 10:18 · Berean Standard Bible

“Why do you call Me good?” Jesus replied. “No one is good except God alone.

Context

16Nígbà náà, Jesu gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn. 17Bí Jesu ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” 18Jesu béèrè pé, arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere. 19Ìwọ mọ àwọn òfin bí: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ purọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ” 20Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.