Marku 1:4
Mark 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
Mark 1:4 in English
Mark 1:4 · Berean Standard Bible
John the Baptist appeared in the wilderness, preaching a baptism of repentance for the forgiveness of sins.
Context
2Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé,
“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.” 3“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” 4Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. 5Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 6Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.