Mika 6:4
Micah 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.
Micah 6:4 in English
Micah 6:4 · Berean Standard Bible
For I brought you up from the land of Egypt and redeemed you from the house of slavery. I sent Moses before you, as well as Aaron and Miriam.
Context
2“Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa;
gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé.
Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́;
òun yóò sì bá Israẹli rojọ́. 3“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?
Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn. 4Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá.
Mo rán Mose láti darí yín,
bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀. 5Ìwọ ènìyàn mi,
rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò
àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn.
Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali,
kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.” 6Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa
tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga?
Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.