Native Bible

Micah 6:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí: “Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá; sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.

Micah 6:1 in English

Micah 6:1 · Berean Standard Bible

Hear now what the LORD says: “Arise, plead your case before the mountains, and let the hills hear your voice.

Context

1Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí: “Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá; sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí. 2“Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa; gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé. Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́; òun yóò sì bá Israẹli rojọ́. 3“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín? Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.