Mika 5:3
Micah 5:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí, àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli.
Micah 5:3 in English
Micah 5:3 · Berean Standard Bible
Therefore Israel will be abandoned until she who is in labor has given birth; then the rest of His brothers will return to the children of Israel.
Context
1Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ,
ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun,
nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá.
Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. 2“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata,
bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda,
nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli
yóò ti jáde tọ̀ mí wá,
ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́,
láti ìgbà láéláé.” 3Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá
títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí,
àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà
láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli. 4Òun yóò sì dúró,
yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára Olúwa,
ní ọláńlá orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
Wọn yóò sì wà láìléwu,
nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹ
yóò sì dé òpin ayé. 5Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn.
Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ wa
tí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa,
nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i,
àti olórí ènìyàn mẹ́jọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.