Native Bible

Micah 5:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ, ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun, nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá. Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.

Micah 5:1 in English

Micah 5:1 · Berean Standard Bible

Now, O daughter of troops, mobilize your troops; for a siege is laid against us! With a rod they will strike the cheek of the judge of Israel.

Context

1Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ, ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun, nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá. Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. 2“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata, bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé.” 3Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá títí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí, àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padà láti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.