Mika 4:3
Micah 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
Micah 4:3 in English
Micah 4:3 · Berean Standard Bible
Then He will judge between many peoples and arbitrate for strong nations far and wide. Then they will beat their swords into plowshares and their spears into pruning hooks. Nation will no longer take up the sword against nation, nor will they train anymore for war.
Context
1Ní ọjọ́ ìkẹyìn
a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,
àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀. 2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá,
wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu. 3Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,
yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré.
Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀
àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé
orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́. 4Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀
àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,
ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n,
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀. 5Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn,
olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀,
ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa.
Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.