Native Bible

Micah 3:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi; ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;

Micah 3:2 in English

Micah 3:2 · Berean Standard Bible

You hate good and love evil. You tear the skin from my people and strip the flesh from their bones.

Context

1Nígbà náà, ni mo wí pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jakọbu, ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha ni í gba òdodo bí. 2Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi; ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn; 3àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi, wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn. Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò, bí ẹran inú agbada?” 4Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa, ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn. Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.