Native Bible

Micah 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún, èmi yóò sì pohùnréré ẹkún: èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò. Èmi yóò ké bí akátá, èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.

Micah 1:8 in English

Micah 1:8 · Berean Standard Bible

Because of this I will lament and wail; I will walk barefoot and naked. I will howl like a jackal * and mourn like an ostrich.*

Context

6“Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá, bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà. Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì. Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀. 7Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run. Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà, gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.” 8Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún, èmi yóò sì pohùnréré ẹkún: èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò. Èmi yóò ké bí akátá, èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò. 9Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán; ó sì ti wá sí Juda. Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi, àní sí Jerusalẹmu. 10Ẹ má ṣe sọ ní Gati ẹ má ṣe sọkún rárá. Ní ilẹ̀ Beti-Ofra mo yí ara mi nínú eruku.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.