Mika 1:9
Micah 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán; ó sì ti wá sí Juda. Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi, àní sí Jerusalẹmu.
Micah 1:9 in English
Micah 1:9 · Berean Standard Bible
For her wound is incurable; it has reached even Judah; it has approached the gate of my people, as far as Jerusalem itself.
Context
7Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́
gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun,
Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.
Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,
gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.” 8Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún,
èmi yóò sì pohùnréré ẹkún:
èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò.
Èmi yóò ké bí akátá,
èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò. 9Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán;
ó sì ti wá sí Juda.
Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi,
àní sí Jerusalẹmu. 10Ẹ má ṣe sọ ní Gati
ẹ má ṣe sọkún rárá.
Ní ilẹ̀ Beti-Ofra
mo yí ara mi nínú eruku. 11Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú,
ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri.
Àwọn tí ó ń gbé ni Saanani
kì yóò sì jáde wá.
Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀;
a ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.