Mika 1:4
Micah 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn àfonífojì yóò sì pínyà, bí idà níwájú iná, bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
Micah 1:4 in English
Micah 1:4 · Berean Standard Bible
The mountains will melt beneath Him, and the valleys will split apart, like wax before the fire, like water rushing down a slope.
Context
2Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,
fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín,
Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá. 3Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;
yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀. 4Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,
àwọn àfonífojì yóò sì pínyà,
bí idà níwájú iná,
bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́. 5Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí,
àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli.
Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu?
Ǹjẹ́ Samaria ha kọ?
Kí ni àwọn ibi gíga Juda?
Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ? 6“Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá,
bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà.
Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.
Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.