Mika 1:2
Micah 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.
Micah 1:2 in English
Micah 1:2 · Berean Standard Bible
Hear, O peoples, all of you; listen, O earth, and everyone in it! May the Lord GOD bear witness against you, the Lord from His holy temple.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu. 2Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,
fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín,
Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá. 3Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;
yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀. 4Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,
àwọn àfonífojì yóò sì pínyà,
bí idà níwájú iná,
bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.