Native Bible

Matthew 6:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,

Matthew 6:9 in English

Matthew 6:9 · Berean Standard Bible

So then, this is how you should pray: ‘Our Father in heaven, hallowed be Your name.

Context

7Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. 8Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. 9“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín, 10kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe ní ayé bí ti ọ̀run. 11Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.