Native Bible

Matthew 27:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí.

Matthew 27:30 in English

Matthew 27:30 · Berean Standard Bible

Then they spit on Him and took the staff and struck Him on the head repeatedly.

Context

28Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, 29wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” 30Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. 31Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú. 32Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.