Native Bible

Matthew 26:72 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”

Matthew 26:72 in English

Matthew 26:72 · Berean Standard Bible

And again he denied it with an oath: “I do not know the man!”

Context

70Ṣùgbọ́n Peteru sẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.” 71Lẹ́yìn èyí, ní ìta ní ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jesu ti Nasareti.” 72Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.” 73Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa àmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.” 74Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.” Lójúkan náà àkùkọ sì kọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.