Matiu 21:43
Matthew 21:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.
Matthew 21:43 in English
Matthew 21:43 · Berean Standard Bible
Therefore I tell you that the kingdom of God will be taken away from you and given to a people who will produce its fruit.
Context
41Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.” 42Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú Ìwé Mímọ́ pé:
“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
ni ó di pàtàkì igun ilé;
iṣẹ́ Olúwa ni èyí,
ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’? 43“Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá. 44Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.” 45Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi gbọ́ òwe Jesu, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.