Matiu 20:19
Matthew 20:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti náà án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”
Matthew 20:19 in English
Matthew 20:19 · Berean Standard Bible
and will deliver Him over to the Gentiles to be mocked and flogged and crucified. And on the third day He will be raised to life.”
Context
17Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, 18“Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú. 19Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti náà án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.” 20Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀. 21Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”
Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.