Matiu 20:17
Matthew 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé,
Matthew 20:17 in English
Matthew 20:17 · Berean Standard Bible
As Jesus was going up to Jerusalem, He took the twelve disciples aside and said,
Context
15Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’ 16“Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.” 17Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, 18“Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú. 19Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti náà án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.