Native Bible

Matthew 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé, “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”

Matthew 2:15 in English

Matthew 2:15 · Berean Standard Bible

where he stayed until the death of Herod. This fulfilled what the Lord had spoken through the prophet: “Out of Egypt I called My Son.”*

Context

13Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.” 14Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, 15ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé, “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.” 16Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà. 17Nígbà náà ni èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wá ṣẹ pé:

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.