Matiu 2:16
Matthew 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.
Matthew 2:16 in English
Matthew 2:16 · Berean Standard Bible
When Herod saw that he had been outwitted by the Magi, he was filled with rage. Sending orders, he put to death all the boys in Bethlehem and its vicinity who were two years old and under, according to the time he had learned from the Magi.
Context
14Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, 15ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé, “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.” 16Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà. 17Nígbà náà ni èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wá ṣẹ pé: 18“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,
ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá,
Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀.
Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀
nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.